Ezekiel 34:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio si ṣe ijẹ fun awọn keferi mọ, bẹ̃ni ẹranko ilẹ na kì yio pa wọn jẹ, ṣugbọn nwọn o wà li alafia ẹnikẹni kì yio si dẹrùba wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn orílẹ̀ èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́. Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì sí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rù bà wọ́n.