Ezekiel 34:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò mu alailera lara le, bẹ̃ni ẹ kò mu eyiti kò sàn li ara da, bẹ̃ni ẹ kò dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, bẹ̃ni ẹ kò tun mu eyi ti a ti lé lọ padà bọ̀, bẹ̃ni ẹ kò wá eyiti o sọnu, ṣugbọn ipá ati ìka li ẹ ti fi nṣe akoso wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ kò ì tíì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tíì mú aṣàko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò.