Ezekiel 34:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn aguntan mi túká, wọ́n ń káàkiri lórí gbogbo òkè ńlá ati gbogbo òkè kéékèèké. Àwọn aguntan mi fọ́n káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni tí ó bèèrè wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó wá wọn.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn agutàn mi ṣako ni gbogbo òke, ati lori gbogbo òke kékèké, nitõtọ, a tú ọwọ́-ẹran mi ká ilẹ gbogbo, ẹnikẹni kò bere wọn ki o si wá wọn lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn.