Ezekiel 34:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun fi ara rẹ̀ búra ó ní, ‘Àwọn aguntan mi di ìjẹ, fún gbogbo ẹranko nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́; nítorí pé àwọn tí ń ṣọ́ wọn kò wá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oúnjẹ ni wọ́n ń wá sẹ́nu ara wọn, wọn kò bọ́ àwọn aguntan mi.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ, nitori ti ọwọ́-ẹran mi di ijẹ, ti ọwọ́-ẹran mi di onjẹ fun olukuluku ẹranko igbẹ́, nitoriti kò si oluṣọ́ agutan, bẹ̃ni awọn oluṣọ́ agutan kò wá ọwọ́-ẹran mi ri, ṣugbọn awọn oluṣọ́ agutan bọ́ ara wọn, nwọn kò si bọ́ ọwọ́-ẹran mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, nitorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́ àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò ṣe awárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi,