Ezekiel 35:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi emi o tilẹ ṣe gẹgẹ bi ibinu rẹ, ati gẹgẹ bi ilara rẹ ti iwọ ti lò lati inu irira rẹ si wọn; emi o si sọ ara mi di mimọ̀ lãrin wọn, nigbati emi ba ti da ọ li ẹjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láàyè, ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárin wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ.