Ezekiel 35:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi iwọ ti yọ̀ si ini ile Israeli, nitori ti o di ahoro, bẹ̃li emi o ṣe si ọ; iwọ o di ahoro, iwọ oke Seiri ati gbogbo Idumea, ani gbogbo rẹ̀: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Ísírẹ́lì di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Séírì, ìwọ àti gbogbo ará Édómù. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA.’ ”