Ezekiel 35:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra pé, n óo fi ọ́ fún ikú pa, ikú yóo máa lépa rẹ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́; ikú yóo máa lépa ìwọ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi o pèse rẹ silẹ fun ẹ̀jẹ, ẹ̀jẹ yio si lepa rẹ: bi iwọ kò ti korira ẹ̀jẹ nì, ẹ̀jẹ yio lepa rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí náà bi mo ti wà láàyè, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ kò ti korìíra ìtàjẹ̀-sílẹ̀, ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ.