Ezekiel 36:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu enia ati ẹranko bi si i lori nyin; nwọn o si pọ̀ si i, nwọn o si rẹ̀: emi o si mu nyin joko ni ibugbe nyin, bi ti atijọ, emi o si ṣe si nyin jù igbà ibẹ̀rẹ nyin lọ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni OLÚWA.