Ezekiel 36:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N kò ní jẹ́ kí o gbọ́ ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan kò ní dójútì ọ́ mọ́, n kò sì ní mú kí orílẹ̀-èdè rẹ kọsẹ̀ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni emi kì yio mu ki enia gbọ́ ìtiju awọn keferi ninu rẹ mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio rù ẹ̀gan awọn orilẹ-ède mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio mu ki orilẹ-ẹ̀de rẹ ṣubu mọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀ èdè rẹ ṣubú, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”