Ezekiel 36:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, nigbati ile Israeli ngbe ilẹ ti wọn; nwọn bà a jẹ nipa ọ̀na wọn, ati nipa iṣe wọn: ọ̀na wọn loju mi dabi aimọ́ obinrin ti a mu kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi.