Ezekiel 36:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, wọ́n bà mí lórúkọ jẹ́, nítorí àwọn eniyan ń sọ nípa wọn pé, ‘Eniyan OLUWA ni àwọn wọnyi, sibẹsibẹ wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ OLUWA.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn si wọ̀ inu awọn keferi, nibiti nwọn lọ, nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ, nigbati nwọn wi fun wọn pe, Awọn wọnyi li enia Oluwa, nwọn si ti jade kuro ni ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn OLÚWA, síbẹ̀ wọn ní láti fí ilẹ̀ náà sílẹ̀.’