Ezekiel 36:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina sọ fun ile Israeli, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli, emi kò ṣe eyi nitori ti nyin, ṣugbọn fun orukọ mimọ́ mi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti ẹnyin lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti lọ.