Ezekiel 36:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ orukọ nla mi di mimọ́, ti a bajẹ lãrin awọn keferi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin wọn; awọn keferi yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati a o sọ mi di mimọ́ ninu nyin niwaju wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárin wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀ èdè yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.