Ezekiel 36:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, ó ní kí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé wọ́n ti sọ ẹ̀yin òkè Israẹli di ahoro, wọ́n sì ja yín gbà lọ́tùn-ún lósì, títí tí ẹ fi di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, àwọn eniyan sì ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní ìsọkúsọ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina sọtẹlẹ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Nitõtọ nitori nwọn ti sọ ọ di ahoro, ti nwọn si gbe ọ mì niha gbogbo, ki ẹnyin ba le jẹ ini fun awọn keferi iyokù, ti a mu nyin si ẹnu, ti ẹnyin si jasi ẹ̀gan awọn enia:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdibàjẹ́ sí,