Ezekiel 36:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo jẹ́ kí èso igi ati èrè oko pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ìtìjú kò ní ba yín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ nítorí ìyàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ eso-igi di pupọ̀, ati ibísi oko, ki ẹ má bà gbà ẹ̀gan ìyan mọ lãrin awọn keferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè náà nítorí ìyàn.