Ezekiel 36:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé kì í ṣe nítorí yín ni n óo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ojú tì yín, kí ẹ sì dààmú nítorí ìwà yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì iṣe nitori ti nyin li emi ṣe eyi, ni Oluwa Ọlọrun wi, ẹ mọ̀ eyi: ki oju ki o tì nyin, ki ẹ si dãmú nitori ọ̀na ara nyin, ile Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì!