Ezekiel 36:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ yìí, tí ó ti jẹ́ igbó nígbà kan rí, ti dàbí ọgbà Edẹni, àwọn eniyan sì ti ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n ti wó lulẹ̀, tí wọ́n ti di ahoro, tí wọ́n sì ti run tẹ́lẹ̀; a sì ti mọ odi wọn pada.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si wipe, Ilẹ yi ti o ti di ahoro ti dabi ọgbà Edeni; ati ilu ti o tú, ti o di ahoro, ti o si parun, di ilu olodi, o si ni olugbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ṣíṣòfo tẹ́lẹ̀ ti dà bí ọgbà Édẹ́nì; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsìnyí.”