Ezekiel 36:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi ọwọ́-ẹran mimọ́, bi ọwọ́-ẹran Jerusalemu ni àse wọn ti o ni ironu, bẹ̃ni ilu ti o di ahoro yio kún fun enia: nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jérúsálẹ́mù ní àsìkò àjọ. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”