Ezekiel 36:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, kí ẹ̀yin òkè ńláńlá ati ẹ̀yin òkè kéékèèké Israẹli, ẹ̀yin ipa odò ati ẹ̀yin àfonífojì, ẹ̀yin ibi tí ẹ ti di aṣálẹ̀ ati ẹ̀yin ìlú tí ẹ ti di ahoro, ẹ̀yin ìlú tí ẹ di ìjẹ ati yẹ̀yẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yi yín ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oke-nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, fun ibi idahoro, ati fun awọn ilu ti a kọ̀ silẹ, ti o di ijẹ ati iyọsùtisi fun awọn keferi iyokù ti o yika kiri;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun: Èyí yìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kékèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kékèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà