Ezekiel 36:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“N óo fi ìtara sọ̀rọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati gbogbo Edomu, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ pẹlu ọkàn ìkórìíra sọ ilẹ̀ mi di ogún wọn, kí wọ́n lè gbà á, kí wọ́n sì pín in mọ́wọ́, nítorí wọ́n rò pé ilẹ̀ mi ti di tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitõtọ ninu iná owu mi li emi ti sọ̀rọ si awọn keferi iyokù, ati si gbogbo Idumea, ti o ti fi ayọ̀ inu wọn gbogbo yàn ilẹ mi ni iní wọn, pẹlu àrankan inu, lati ta a nù fun ijẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ lòdì sí Édómù, nítorí pẹ̀lú ayọ̀ àti ìyodì ní ọkàn wọn ní wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’