Ezekiel 36:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Wí fún àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn ipa odò ati àwọn àfonífojì, pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ìtara ati ìgbónára ni mo fi ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ ti jìyà pupọ, ẹ sì ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina sọtẹlẹ niti ilẹ Israeli, ki o si wi fun awọn oke nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Wò o, emi ti sọ̀rọ ninu owu mi, ati ninu irúnu mi, nitori ti ẹnyin ti rù itiju awọn keferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kékèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀ èdè.