Ezekiel 37:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iwọ, ọmọ enia, mu igi kan, si kọwe si i lara, Fun Juda, ati fun awọn ọmọ Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀: si mu igi miran, si kọwe si i lara, Fun Josefu, igi Efraimu, ati fun gbogbo ile Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, mú igi pátakó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Júdà àti ti Ísírẹ́lì tí ó ní àsṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátakó mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Igi tí Éfúraímù jẹ́ ti Jósẹ́fù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’