Ezekiel 37:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ wọn di orilẹ-ède kan ni ilẹ lori oke-nla Israeli; ọba kan ni yio si jẹ lori gbogbo wọn: nwọn kì yio si jẹ orilẹ-ède meji mọ, bẹ̃ni a kì yio sọ wọn di ijọba meji mọ rara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Ísírẹ́lì, Ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.