Ezekiel 37:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo máa gbé ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín gbé. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn ati àwọn ọmọ ọmọ wọn yóo máa gbé ibẹ̀ títí lae. Dafidi iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba wọn títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si ma gbe ilẹ ti emi ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi, nibiti awọn baba nyin ti gbe; nwọn o si ma gbe inu rẹ̀, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ ọmọ wọn lailai: Dafidi iranṣẹ mi yio si ma jẹ ọmọ-alade wọn lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, Ìránṣẹ́ mi Dáfídì ni yóò jẹ́ ọmọ Aládé wọn láéláé.