Ezekiel 37:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu emi o ba wọn dá majẹmu alafia; yio si jẹ majẹmu aiyeraiye pẹlu wọn: emi o si gbe wọn kalẹ, emi o si mu wọn rẹ̀, emi o si gbe ibi mimọ́ mi si ãrin wọn titi aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò dá májẹ̀mu àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mu títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì ṣọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárin wọn títí láé.