Ezekiel 38:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
o óo wí ninu ara rẹ pé, ‘N óo gbógun ti ilẹ̀ tí kò ní odi yìí; n óo kọlu àwọn tí wọ́n jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ wọn láìléwu, gbogbo wọn ń gbé ìlú tí kò ní odi, kò sì ní ìlẹ̀kùn, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si wipe, emi o goke lọ si ilẹ ileto ti kò ni odi: emi o tọ̀ awọn ti o wà ni isimi lọ, ti nwọn ngbe laibẹ̀ru, ti gbogbo wọn ngbe laisi odi, ti nwọn kò si ni agbarà-irin tabi ẹnu-odi,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé Ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká: Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò furasí-gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu ọ̀nà òde àti àsígbà.