Ezekiel 38:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo lọ kó wọn lẹ́rù, n óo sì kó ìkógun. N óo kọlu àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro nígbà kan rí, ṣugbọn tí àwọn eniyan ń gbé ibẹ̀ nisinsinyii, àwọn eniyan tí a ṣà jọ láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, ṣugbọn tí wọ́n ní mààlúù ati ohun ìní, tí wọ́n sì ń gbé ìkóríta ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati lọ kó ikogun, ati lati lọ mu ohun ọdẹ; lati yi ọwọ́ rẹ si ibi ahoro wọnni ti a tẹ̀do nisisiyi, ati si enia ti a kojọ lati inu awọn orilẹ-ède wá, awọn ti o ti ni ohun-ọ̀sin ati ẹrù, ti ngbe oke ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú nǹkan ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ náà.”