Ezekiel 38:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí pé, OLUWA Ọlọrun ní: “Ní ọjọ́ tí àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, bá ń gbé láìléwu, ìwọ óo gbéra ní ààyè rẹ
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, sọtẹlẹ, ọmọ enia, si wi fun Gogu pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ni ijọ na nigbati awọn enia mi Israeli ba ngbe laibẹ̀ru, iwọ kì yio mọ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí ó sì ṣọ fún Gógì: ‘Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀?