Ezekiel 38:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ní ọ̀nà jíjìn, ní ìhà àríwá, ìwọ ati ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn lórí ẹṣin, ọpọlọpọ eniyan, àní, àwọn ọmọ ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ti ipò rẹ wá lati iha ariwa, iwọ, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ, gbogbo wọn li o ngùn ẹṣin, ẹgbẹ nla, ati ọ̀pọlọpọ ogun alagbara:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹsìn ìjọ ńlá, jagunjagun alágbára.