Ezekiel 38:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O óo kọlu àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan mi, bí ìkùukùu tí ń ṣú bo ilẹ̀. Nígbà tí ó bá yà n óo mú kí o kọlu ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè mọ̀ mí nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ ìwọ Gogu fi bí ìwà mímọ́ mi ti rí hàn níṣojú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si goke wá si awọn enia mi Israeli, bi awọsanma lati bò ilẹ; yio si ṣe nikẹhin ọjọ, emi o si mu ọ dojukọ ilẹ mi, ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ mi, nigbati a o yà mi si mimọ́ ninu rẹ, niwaju wọn, iwọ Gogu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gógì, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀ èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fí ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.