Ezekiel 38:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: ṣé ìwọ ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ láti ẹnu àwọn wolii Israẹli, àwọn iranṣẹ mi, tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọpọlọpọ ọdún pé n óo mú ọ wá láti gbógun tì wọ́n?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ li ẹniti mo ti sọ̀rọ rẹ̀ nigba atijọ lati ọwọ́ awọn iranṣẹ mi awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ li ọjọ wọnni li ọdun pupọ pe, emi o mu ọ wá dojukọ wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Ìwọ ha kọ́ ni mo ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi ti Ísírẹ́lì? Ní ìgbà náà wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn.