Ezekiel 38:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú ogun ṣe ìdájọ́ wọn. N óo rọ òjò yìnyín, iná, ati imí ọjọ́ lé òun, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan pupọ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si fi ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ ba a wijọ; emi o si rọ̀ ojò pupọ̀, ati yìnyin nla, iná ati imi-ọjọ, si i lori, ati sori áwọn ẹgbẹ rẹ̀, ati sori ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀sílẹ̀; Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.