Ezekiel 38:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fi títóbi mi ati ìwà mímọ́ mi hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si gbe ara mi lèke, emi o si ya ara mi si mimọ́; emi o si di mimọ̀ loju ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.’