Ezekiel 38:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo yí ojú rẹ pada, n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì mú ọ jáde, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ, ati àwọn ati ẹṣin wọn, gbogbo wọn, tàwọn ti ihamọra wọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ní asà ati apata, tí wọ́n sì ń fi idà wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si dá ọ padà, emi o si fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si mu ọ jade wá, ati gbogbo ogun rẹ, ẹṣin ati ẹlẹṣin, gbogbo wọn li a wọ̀ laṣọ daradara, ani ẹgbẹ́ nla pẹlu apata on asà, gbogbo wọn dì idà mu:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹsinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèkéé, gbogbo wọn ń fi idà wọn.