Ezekiel 38:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhìn ọjọ pupọ̀ li a o bẹ̀ ọ wò: li ọdun ikẹhìn, iwọ o wá si ilẹ ti a gbà padà lọwọ idà, ti a si kojọ pọ̀ kuro lọdọ enia pupọ̀, lori oke-nla Israeli, ti iti ma di ahoro: ṣugbọn a mu u jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, nwọn o si ma gbe li ailewu, gbogbo wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò pè ọ́ fún àwọn ohun èlò ogun. Ní àwọn ọdún ọjọ́ iwájú ìwọ yóò dóti ilẹ̀ tí a ti gbà nígbà ogun, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè sí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, nísínsínyìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu.