Ezekiel 38:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo gbéra, ẹ óo máa bọ̀ bí ìjì líle, ẹ óo dàbí ìkùukùu tí ó bo ilẹ̀, ìwọ ati gbogbo ọmọ ogun rẹ, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tí ó wà pẹlu rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o goke wá, iwọ o si de bi ijì, iwọ o dabi awọsanma lati bò ilẹ, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati ọ̀pọlọpọ enia pẹlu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀ṣíwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ìlẹ̀ mọ́lẹ̀.