Ezekiel 39:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Fún ọdún meje yìí, ẹnìkan kò ní ṣẹ́ igi ìdáná lóko, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gé igi ninu igbó kí wọ́n tó dáná; ohun ìjà ogun ni wọn yóo máa fi dáná. Wọn yóo kó ẹrù àwọn tí wọ́n ti kó wọn lẹ́rù rí; wọn yóo fi ogun kó àwọn ìlú tí wọ́n ti fi ogun kó wọn rí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò ní nílo láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lé òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni OLÚWA Ọba tẹnumọ́.