Ezekiel 39:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Tí ó bá di ìgbà náà, n óo fún Gogu ní ibi tí wọn yóo sin ín sí ní Israẹli, àní àfonífojì àwọn arìnrìnàjò tí ó wà ní ìlà oòrùn Òkun Iyọ̀. Yóo dínà mọ́ àwọn arìnrìnàjò nítorí níbẹ̀ ni a óo sin Gogu ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ sí. A óo sì máa pè é ní àfonífojì Hamoni Gogu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, emi o fi ibikan fun Gogu nibẹ fun iboji ni Israeli, afonifoji awọn èro ni gabasi okun; on si pa awọn èro ni ẹnu mọ: nibẹ ni nwọn o gbe sin Gogu ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ si: nwọn o si pè e ni, Afonifoji Hamon-gogu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gógì ní Ísírẹ́lì, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà òòrùn òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn àjò, nítorí Gógì àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a óò pè é ní àfonífojì tí Ámónì Gógì.