Ezekiel 39:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn oṣù meje wọn yóo yan àwọn kan tí wọn óo la ilẹ̀ náà já, tí wọn óo máa wá òkú tí ó bá kù nílẹ̀, tí wọn óo sì máa sin wọ́n kí wọ́n lè sọ ilẹ̀ náà di mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si yà awọn ọkunrin sọtọ ti yio ma fi ṣe iṣẹ iṣe, lati ma rìn ilẹ na ja lati lọ isin awọn erò ti o kù lori ilẹ, lati sọ ọ di mimọ́: lẹhin oṣù meje nwọn o ma wá kiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ lóòrèkóórè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tó kù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù kéje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn.