Ezekiel 39:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí OLÚWA Ọba wí pé: pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ jáde:” kí wọn pé jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Ísírẹ́lì. Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀.