Ezekiel 39:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran Ọlọ́ràá láti Báṣánì