Ezekiel 39:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li a o fi ẹṣin ati ẹlẹṣin bọ́ nyin yo lori tabili mi, pẹlu awọn alagbara, ati gbogbo awọn ologun, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́sin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìríṣìí jagunjagun ni OLÚWA Ọba sọ.