Ezekiel 39:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli n óo kó àwọn ọmọ Jakọbu pada láti oko ẹrú, n óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì jowú nítorí orúkọ mímọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nisisiyi li emi o mu igbèkun Jakobu padà bọ̀, emi o si ṣãnu fun gbogbo ile Israeli, emi o si jowu nitori orukọ mi mimọ́:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà èyí ni ohun tí OLÚWA Ọba wí: Èmi yóò mú Jákọ́bù padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní iyọ́nú si gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi.