Ezekiel 39:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí mo bá kó wọn pada láti inú oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè, tí mo kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n óo fi ara mi hàn bí ẹni mímọ́ lójú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi ti mu wọn bọ̀ lati ọdọ orilẹ-ède, ti mo si ko wọn jọ lati ilẹ awọn ọta wọn wá, ti a si yà mi si mimọ́ ninu wọn niwaju orilẹ-ède pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀.