Ezekiel 39:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, nítorí pé mo kó wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, mo sì tún kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn. N kò ní fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀ sí ààrin orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn, nipa kikó ti mo mu ki a kó wọn lọ si igbekun lãrin awọn keferi: ṣugbọn mo ti ṣà wọn jọ si ilẹ wọn, emi kò si fi ẹnikẹni wọn silẹ nibẹ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láì fi ìkankan sẹ́yìn.