Ezekiel 39:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ orukọ mimọ́ mi di mimọ̀ lãrin enia mi Israeli; emi kì yio si jẹ ki nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ mọ: awọn orilẹ-ède yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrin àwọn èniyàn mì Isìrẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ èdè yóò mọ̀ pé èmi OLÚWA, èmi ni ẹni mímọ́ ní Ísírẹ́lì.