Ezekiel 4:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, n kò sọ ara mi di aláìmọ́ rí láti ìgbà èwe mi títí di ìsinsìnyìí, n kò jẹ òkú ẹran rí, tabi ẹran tí ẹranko pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kankan kò kan ẹnu mi rí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo wipe, A, Oluwa Ọlọrun! kiye si i, a kò ti sọ ọkàn mi di aimọ́: nitori lati igba ewe mi wá titi di isisiyi, emi kò ti ijẹ ninu ohun ti o kú fun ara rẹ̀, tabi ti a faya pẹrẹpẹrẹ, bẹ̃ni ẹran ẽwọ̀ kò iti iwọ̀ mi li ẹnu ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo wí pé, “Áà! kò rí bẹ́ẹ̀ OLÚWA Ọlọ́run! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsìnyìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”