Ezekiel 4:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún fi kun fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, n óo mú kí oúnjẹ wọ́n ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rù ni wọn óo máa fi wá oúnjẹ tí wọn óo máa jẹ, wíwọ̀n ni wọn óo sì máa wọn omi mu pẹlu ìpayà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, kiye si i, emi o ṣẹ ọpá onjẹ ni Jerusalemu: nwọn o si jẹ akara nipa ìwọn, ati pẹlu itọju; nwọn o si mu omi nipa ìwọn ati pẹlu iyanu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jérúsálẹ́mù. Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ́ jẹ pẹ̀lú ìfọ̀kansọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú,