Ezekiel 4:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si mu alikama, ati ọka bàba, erẽ ati lentile ati milleti, ati ẹwẹ, fi wọn sinu ikoko kan, ki o si fi wọn ṣe akara, gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ li ẹgbẹ́ rẹ, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ ni iwọ o jẹ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá.