Ezekiel 40:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnu ọ̀nà náà. Bákan náà ni ìwọ̀n àwọn yàrá mẹtẹẹta rí. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwọ̀n àtẹ́rígbà wọn, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ẹnu ọ̀nà ìlà òòrùn ni àwọn yàrá kéékèèkéé mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n.